Lines Matching refs:o

7 Bí ó ti jé̩ pé àìka àwo̩n è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn sí àti ìké̩gàn àwo̩n è̩tó̩ wò̩nyí ti s̩e okùnfà fún àwo̩n ìwà búburú kan, tó mú è̩rí‐o̩kàn è̩dá gbo̩gbé̩, tó sì jé̩ pé ìbè̩rè̩ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwo̩n ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrò̩ síso̩ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wó̩n gbó̩, òmìnira ló̩wó̩ è̩rù àti òmìnira ló̩wó̩ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lo̩ ló̩kàn àwo̩n o̩mo̩‐èniyàn,
9 Bí ó ti jé̩ pé ó s̩e pàtàkì kí a dáàbò bo àwo̩n è̩tó o̩mo̩nìyàn lábé̩ òfin, bí a kò bá fé̩ ti àwo̩n ènìyàn láti ko̩jú ìjà sí ìjo̩ba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ò̩nà àbáyo̩ mìíràn fún wo̩n láti bèèrè è̩tó̩ wo̩n,
13 Bí ó ti jé̩ pé gbogbo o̩mo̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé tún ti te̩nu mó̩ ìpinnu tí wó̩n ti s̩e té̩lè̩ nínú ìwé àdéhùn wo̩n, pé àwo̩n ní ìgbàgbó̩ nínú è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí, ìgbàgbó̩ nínú iyì àti è̩ye̩ è̩dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̩ nínú ìdó̩gba è̩tó̩ láàrin o̩kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̩ pé wó̩n tún ti pinnu láti s̩e ìgbéláruge̩ ìtè̩síwájú àwùjo̩ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé‐ayé rere è̩dá ti lè gbòòrò sí i,
15 Bí ó ti jé̩ pé àwo̩n o̩mo̩ e̩gbé̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé ti jé̩jè̩é̩ láti fo̩wó̩s̩owó̩ pò̩ pè̩lú Àjo̩ náà, kí won lè jo̩ s̩e às̩eyege nípa àmús̩e̩ àwo̩n è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn àti òmìnira è̩dá tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí àti láti rí i pé à ń bò̩wò̩ fún àwo̩n è̩tó̩ náà káríayé,
21 Àpapò̩ ìgbìmò̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé s̩e ìkéde káríayé ti è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn, gé̩gé̩ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̩dá àti orílè̩‐èdè jo̩ ń lépa ló̩nà tó jé̩ pé e̩nì kò̩ò̩kan àti è̩ka kò̩ò̩kan láwùjo̩ yóò fi ìkéde yìí só̩kàn, tí wo̩n yóò sì rí i pé àwo̩n lo ètò‐ìkó̩ni àti ètò‐è̩kó̩ láti s̩e ìgbéláruge̩ ìbò̩wò̩ fún è̩tó̩ àti òmìnira wò̩nyí. Bákan náà, a gbo̩dò̩ rí àwo̩n ìgbésè̩ tí ó lè mú ìlo̩síwájú bá orílè̩‐èdè kan s̩os̩o tàbí àwo̩n orílè̩‐èdè sí ara wo̩n, kí a sì rí i pé a fi ò̩wò̩ tó jo̩jú wo̩ àwo̩n òfin wò̩nyí, kí àmúlò wo̩n sì jé̩ káríayé láàrin àwo̩n ènìyàn orílè̩‐èdè tó jé̩ o̩mo̩ Àjo̩‐ìsò̩kan àgbáyé fúnra wo̩n àti láàrin àwo̩n ènìyàn orílè̩‐èdè mìíràn tó wà lábé̩ às̩e̩ wo̩n.
24 Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti è̩tó̩ kò̩ò̩kan sì dó̩gba. Wó̩n ní è̩bùn ti làákàyè àti ti è̩rí‐o̩kàn, ó sì ye̩ kí wo̩n ó máa hùwà sí ara wo̩n gé̩gé̩ bí o̩mo̩ ìyá.
37 A kò gbo̩dò̩ dá e̩nì ké̩ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò ye̩ o̩mo̩ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù è̩dá ènìyàn.
46 E̩nì kò̩ò̩kan lórílè̩‐èdè, ló ní è̩tó̩ sí àtúns̩e tó jo̩jú ní ilé‐e̩jó̩ fún ìwà tó lòdì sí è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn, tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí gé̩gé̩ bó s̩e wà lábé̩ òfin àti bí òfin‐ìpìlè̩ s̩e là á sílè̩.
73 1. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti jé̩ o̩mo̩ orílè̩‐èdè kan.
75 2. A kò lè s̩àdédé gba è̩tó̩ jíjé̩ o̩mo̩ orílè̩‐èdè e̩ni ló̩wó̩ e̩nìké̩ni láìnídìí tàbí kí a kò̩ fún e̩nìké̩ni láti yàn láti jé̩ o̩mo̩ orílè̩‐èdè mìíràn.
90 E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí òmìnira èrò, òmìnira è̩rí‐o̩kàn àti òmìnira e̩ sìn. E̩tó̩ yìí sì gbani láàyè láti pààrò̩ e̩ sìn tàbí ìgbàgbó̩ e̩ni. Ó sì fún e̩yo̩ e̩nì kan tàbí àkójo̩pò̩ ènìyàn láàyè láti s̩e è̩sìn wo̩n àti ìgbàgbó̩ wo̩n bó s̩e je̩ mó̩ ti ìkó̩ni, ìs̩esí, ìjó̩sìn àti ìmús̩e ohun tí wó̩n gbàgbó̩ yálà ní ìkò̩kò̩ tàbí ní gban̄gba.
105 3. I fé̩ àwo̩n ènìyàn ìlú ni yóò jé̩ òkúta ìpìlè̩ fún à s̩e̩ ìjo̩ba; a ó máa fi ìfé̩ yìí hàn nípasè̩ ìbò tòótó̩ tí a ó máa dì láti ìgbà dé ìgbà, nínú èyí tí e̩nì kò̩ò̩kan yóò ní è̩tó̩ sí ìbò kan s̩os̩o tí a dì ní ìkò̩kò̩ tàbí nípasè̩ irú o̩ nà ìdìbò mìíràn tí ó bá irú ìdìbò bé̩è̩ mu.
108 E̩nì kò̩ò̩kan gé̩gé̩ bí è̩yà nínú àwùjo̩ ló ní è̩tó̩ sí ìdáàbò bò láti o̩wó̩ ìjo̩ba àti láti jé̩ àn fà ní àwo̩n è̩tó̩ tí ó bá o̩rò̩‐ajé, ìwà láwùjo̩ àti às̩à àbínibí mu; àwo̩n è̩tó̩ tí ó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí fún iyì àti ìdàgbàsókè è̩dá ènìyàn, nípa akitiyan nínú orílè̩‐èdè àti ìfo̩wó̩s̩owó̩ pò̩ láàrin àwo̩n orílè̩‐èdè ní ìbámu pè̩lú ètò àti ohun àlùmó̩nì orílè̩‐èdè kò̩ò̩kan.
123 1. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tí òun àti e̩bí rè̩ yóò wà ní ìlera àti àlàáfíà, tí wo̩n yóò sì ní oúnje̩, as̩o̩, ilégbèé, àti àn fàní fún ìwòsàn àti gbogbo ohun tó lè mú è̩dá gbé ìgbé ayé rere. Bákan náà, e̩nì kò̩ò̩kan ló tún ní ààbò nígbà àìnís̩é̩ló̩wó̩, nígbà àìsà n, nígbà tó bá di aláàbò̩‐ara, ní ipò opó, nígbà ogbó rè̩ tàbí ìgbà mìíràn tí ènìyàn kò ní ò̩nà láti rí oúnje̩ òò jó̩, tí eléyìí kì í sì í s̩e è̩bi olúwa rè̩.
125 2. A ní láti pèsè ìtó̩jú àti ìrànló̩wó̩ pàtàkì fún àwo̩n abiyamo̩ àti àwo̩n o̩mo̩dé. Gbogbo àwo̩n o̩mo̩dé yóò máa je̩ àwo̩n àn fàní ààbò kan náà nínú àwùjo̩ yálà àwo̩n òbí wo̩n fé̩ ara wo̩n ni tàbí wo̩n kò fé̩ ara wo̩n.
128 1. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti kó̩ è̩kó̩. Ó kéré tán, è̩kó̩ gbo̩dò̩ jé̩ ò̩fé̩ ní àwo̩n ilé‐è̩kó̩ alákò̩ó̩bè̩rè̩. E̩kó̩ ní ilé‐è̩kó̩ alákò̩ó̩bè̩rè̩ yìí sì gbo̩dò̩ jé̩ dandan. A gbo̩dò̩ pèsè è̩kó̩ is̩é̩‐o̩wó̩, àti ti ìmò̩‐è̩ro̩ fún àwo̩n ènìyàn lápapò̩. Àn fàní tó dó̩gba ní ilé‐è̩kó̩ gíga gbo̩dò̩ wà ní àró̩wó̩tó gbogbo e̩ni tó bá tó̩ sí.
130 2. Ohun tí yóò jé̩ ète è̩kó̩ ni láti mú ìlo̩síwájú tó péye bá è̩dá ènìyàn, kí ó sì túbò̩ rí i pé àwo̩n ènìyàn bò̩wò̩ fún è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn àti àwo̩n òmìnira wo̩n, tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí. E tò è̩kó̩ gbo̩dò̩ lè rí i pé è̩mí; ìgbó̩ra‐e̩ni‐yé, ìbágbépò̩ àlàáfíà, àti ìfé̩ ò̩ré̩‐sí‐ò̩ré̩ wà láàrin orílè̩‐èdè, láàrin è̩yà kan sí òmíràn àti láàrin e̩lé̩sìn kan sí òmíràn. E tò‐è̩kó̩ sì gbo̩dò̩ kún àwo̩n akitiyan Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé ló̩wó̩ láti rí i pé àlàáfíà fìdí múlè̩.
132 3. Àwo̩n òbí ló ní è̩tó̩ tó ga jù lo̩ láti yan è̩kó̩ tí wó̩n bá fé̩ fún àwo̩n o̩mo̩ wo̩n.
137 2. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí ààbò àn fàní ìmo̩yì àti ohun ìní tí ó je̩ yo̩ láti inú is̩é̩ yòówù tí ó bá s̩e ìbáà s̩e ìmò̩ sáyé̩n sì, ìwé kíko̩ tàbí is̩é̩ o̩nà.
148 Abala o̩gbò̩n.