Lines Matching refs:i
13 Bí ó ti jé̩ pé gbogbo o̩mo̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé tún ti te̩nu mó̩ ìpinnu tí wó̩n ti s̩e té̩lè̩ nínú ìwé àdéhùn wo̩n, pé àwo̩n ní ìgbàgbó̩ nínú è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí, ìgbàgbó̩ nínú iyì àti è̩ye̩ è̩dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̩ nínú ìdó̩gba è̩tó̩ láàrin o̩kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̩ pé wó̩n tún ti pinnu láti s̩e ìgbéláruge̩ ìtè̩síwájú àwùjo̩ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé‐ayé rere è̩dá ti lè gbòòrò sí i,
15 Bí ó ti jé̩ pé àwo̩n o̩mo̩ e̩gbé̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé ti jé̩jè̩é̩ láti fo̩wó̩s̩owó̩ pò̩ pè̩lú Àjo̩ náà, kí won lè jo̩ s̩e às̩eyege nípa àmús̩e̩ àwo̩n è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn àti òmìnira è̩dá tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí àti láti rí i pé à ń bò̩wò̩ fún àwo̩n è̩tó̩ náà káríayé,
21 Àpapò̩ ìgbìmò̩ Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé s̩e ìkéde káríayé ti è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn, gé̩gé̩ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̩dá àti orílè̩‐èdè jo̩ ń lépa ló̩nà tó jé̩ pé e̩nì kò̩ò̩kan àti è̩ka kò̩ò̩kan láwùjo̩ yóò fi ìkéde yìí só̩kàn, tí wo̩n yóò sì rí i pé àwo̩n lo ètò‐ìkó̩ni àti ètò‐è̩kó̩ láti s̩e ìgbéláruge̩ ìbò̩wò̩ fún è̩tó̩ àti òmìnira wò̩nyí. Bákan náà, a gbo̩dò̩ rí àwo̩n ìgbésè̩ tí ó lè mú ìlo̩síwájú bá orílè̩‐èdè kan s̩os̩o tàbí àwo̩n orílè̩‐èdè sí ara wo̩n, kí a sì rí i pé a fi ò̩wò̩ tó jo̩jú wo̩ àwo̩n òfin wò̩nyí, kí àmúlò wo̩n sì jé̩ káríayé láàrin àwo̩n ènìyàn orílè̩‐èdè tó jé̩ o̩mo̩ Àjo̩‐ìsò̩kan àgbáyé fúnra wo̩n àti láàrin àwo̩n ènìyàn orílè̩‐èdè mìíràn tó wà lábé̩ às̩e̩ wo̩n.
27 E̩nì kò̩ò̩kan ló ní ànfàní sí gbogbo è̩tó̩ àti òmìnira tí a ti gbé kalè̩ nínú ìkéde yìí láìfi ti ò̩rò̩ ìyàtò̩ è̩yà kankan s̩e; ìyàtò̩ bí i ti è̩yà ènìyàn, àwò̩, ako̩‐n̄‐bábo, èdè, è̩sìn, ètò ìs̩èlú tàbí ìyàtò̩ nípa èrò e̩ni, orílè̩‐èdè e̩ni, orírun e̩ni, ohun ìní e̩ni, ìbí e̩ni tàbí ìyàtò̩ mìíràn yòówù kó jé̩. Síwájú sí i, a kò gbo̩dò̩ ya e̩nìké̩ni só̩tò̩ nítorí irú ìjo̩ba orílè̩‐èdè rè̩ ní àwùjo̩ àwo̩n orílè̩‐èdè tàbí nítorí ètò‐ìs̩èlú tàbí ètò‐ìdájó̩ orílè̩‐èdè rè̩; orílè̩‐èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábé̩ ìs̩àkóso ilè̩ mìíràn, wo̩n ìbáà má dàá ìjo̩ba ara wo̩n s̩e tàbí kí wó̩n wà lábé̩ ìkáni‐lápá‐kò yòówù tí ìbáà fé̩ dí òmìnira wo̩n ló̩wó̩ gé̩gé̩ bí orílè̩‐èdè.
60 E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ pé kí a má s̩àdédé s̩e àyo̩júràn sí ò̩rò̩ ìgbésí ayé rè̩, tàbí sí ò̩rò̩e̩bí rè̩ tàbí sí ò̩rò̩ ìdílé rè̩ tàbí ìwé tí a ko̩ sí i; a kò sì gbo̩dò̩ ba iyì àti orúko̩ rè̩ jé̩. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ sí ààbò lábé̩ òfin kúrò ló̩wó̩ irú àyo̩júràn tàbí ìbanijé̩ bé̩è̩.
68 1. E̩nì kò̩ò̩kan ló ní è̩tó̩ láti wá ààbò àti láti je̩ àn fàní ààbò yìí ní orílè̩‐èdè mìíràn nígbà tí a bá ń s̩e inúnibíni sí i.
130 2. Ohun tí yóò jé̩ ète è̩kó̩ ni láti mú ìlo̩síwájú tó péye bá è̩dá ènìyàn, kí ó sì túbò̩ rí i pé àwo̩n ènìyàn bò̩wò̩ fún è̩tó̩ o̩mo̩nìyàn àti àwo̩n òmìnira wo̩n, tó jé̩ kò‐s̩eé‐má‐nìí. E tò è̩kó̩ gbo̩dò̩ lè rí i pé è̩mí; ìgbó̩ra‐e̩ni‐yé, ìbágbépò̩ àlàáfíà, àti ìfé̩ ò̩ré̩‐sí‐ò̩ré̩ wà láàrin orílè̩‐èdè, láàrin è̩yà kan sí òmíràn àti láàrin e̩lé̩sìn kan sí òmíràn. E tò‐è̩kó̩ sì gbo̩dò̩ kún àwo̩n akitiyan Àjo̩‐ìsò̩kan orílè̩‐èdè àgbáyé ló̩wó̩ láti rí i pé àlàáfíà fìdí múlè̩.